Ẹ̀rù
ló sọ ọmọ Ẹkùn di lógbò/Ológìní tó fi di “Ẹran-àmúsìn – Ọdẹ peku-peku”
Ni igbà àtijọ́,
ẹranko ti
wọn pè ni Ẹkùn jẹ alágbára ẹranko, bẹni Kìnìún si jẹ́ alágbára
ẹranko. Bi Kìnìún ti lágbára tó ninú igbó, bi ó bá bú
ramúramù, ohun gbogbo ninú igbó á pa kẹ́kẹ́ titi dé ori ẹranko yoku. Ti
Ẹkùn nikan ló yàtọ̀, nitori Ọlọrun fún ni ẹ̀bùn igbóyà, idi niyi ti a fi
ńpè ni “Baba Ẹranko”, ti a ńpè Kìnìún ni “Ọlọ́là Ijù”.
Ni ọjọ́ kan, Ẹkùn
gbéra lọ sinú igbó lati lọ wa oúnjẹ fún àwọn ọmọ rẹ, àwọn ọmọ ẹ kéré
wọn kò lè yára bi iyá wọn. Ó fún wọn ni imọ̀ràn pe ki wọn kó ara
pọ̀ si ibi òkiti-ọ̀gán ti ohun ti lè tètè ri wọn, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́dọ̀
bẹ̀rù fún ohunkóhun tàbi ẹranko ti ó bá wá si sàkáni wọn.
Gẹgẹ bi a ṣe mọ,
Kìnìún àti Ẹkùn, ọ̀gá ni onikálùkù láyé ara wọn, wọn ki ja. Ibi
ti Kìnìún bá wà Ẹkùn kò ni dé ibẹ̀, ibi ti Ẹkùn bá wà Kìnìún ò ni
dé ibẹ̀. Nitori èyi ni Yorùbá fi npa lowe pé “Kàkà ki Kìnìún ṣe
akápò Ẹkùn, onikálùkù yio má ba ọdẹ rẹ̀ lọ”.
Lai fà ọ̀rọ̀ gùn
àwọn ọmọ Ẹkùn gbọ́ igbe Kìnìún, wọn ri ti ó ré kọja, àwọn ọmọ Ẹkùn ti
ẹ̀rù ba ti kò ṣe bi iyá wọn ti ṣe ìkìlọ̀, ìjáyà bá wọn, wọ́n sá.
Nigbati Ẹkùn dé ibùdó rẹ lati fún àwọn ọmọ rẹ ni ẹran jẹ, àwọn ọmọ rẹ
kò pé, ṣ̀ugbọ́n àwọn ọmọ ti ijáyà bá padà wá bá iyá wọn, nigbà yi ni
iyá wọn rán wọn leti ikilọ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jáyà. Nitori èyi,
ohun kọ̀ wọ́n lọ́mọ.
Nigbati iyá wọn kọ̀
wọ́n lọ́mọ, wọn kò lè ṣe ọdẹ inú igbó mọ́, wọn di ẹranko tó ńrágó, ti
wọn ńsin ninú ilé, to ńpa eku kiri. Idi èyi ni Yorùbá fi npa ni
òwe pé “Ìjayà ló bá ọmọ Ẹkùn ti ó di Ológbò ti ó ńṣe ọde eku inú
ilé.
Tradução
Nos tempos antigos, o "Tigre" era um animal
poderoso, assim como o Leão, que era muito poderoso. Quando o Leão rugia, tudo
na selva ficava em silêncio. Somente o Tigre era diferente porque ele / ela era
dotado de ousadia. Daí ele ser chamado de "Pai dos animais" enquanto
o Leão é conhecido como "Rei da Selva".
Um dia, a tigresa deixou o seu lugar na selva para ir buscar
comida para seus filhotes que não eram tão rápidos quanto sua ela. Ela os
instruiu para se reunissem e ficassem em cima de um monte, onde ela poderia
vê-los rapidamente. Instrui-os também que eles não deviam ter medo de nada nem
de outros animais que se aproximassem deles.
Como é sabido, o Leão e o Tigre eram chefes com muita
propriedade em seus respectivos direitos. Eles nunca lutaram. Onde quer que o
Tigre fosse, o Leão não cruzaria, e vice-versa. Como resultado, o provérbio
Yoruba disse: "Em vez do Leão se tornar o tesoureiro do Tigre, cada um
segue seus caminhos em separado".
Para não prolongar o assunto, os filhotes da Tigresa
ouviram o rugido do Leão quando este passou perto deles. Aí alguns dos filhotes
sentiram medo e desobedeceram a instrução de sua mãe para não terem medo, e então
eles correram.
Quando a Tigresa chegou com a presa para alimentar seus
filhotes, eles estavam incompletos. Mais tarde aqueles que haviam fugido, voltaram.
Encontraram a mãe que lembrou suas instruções para não temer. Como resultado da
desobediência, ela os desprezou.
Como sua mãe os rejeitou, eles cresceram sem aprender a
caçar e não conseguiram sobreviver na selva, e não sobrou para eles outra
alternativa a não ser se tornar animais domesticados e viver caçando ratos.
É por isso que o
provérbio Yoruba diz: "É o medo que transformou o filhote do tigre no gato
que caça os ratos da casa".
Referencias:
1. The Yoruba blog; http://www.theyorubablog.com/eru-lo-so-omo-ekun-di-ologboologini-to-n%e1%b9%a3e-ode-ile-kiri-ode-peku-peku-it-is-fear-that-turned-the-tiger/ (acessado em
26/02/18).
(acessado em 27/02/18)
No comments:
Post a Comment