Saturday, December 31, 2022

Ẹ kaabọ̀ si ìlú Slvador, Ojogbọ́n Babalawo Ogundeji Ifadamitan Elebuibon!



Mo ki eyin baba mi, mo ki eyin Ìyá mi.

Mo ki eyin Ẹgbọn mi ati aburo mi fún ayeye ọdún yìí.

Mo bÈù lẹ́gbára,ki ó fún wa ni ọ̀na ti o dará, ti o si ye kooro.

Jẹ́ ki a ki Èṣù ni ṣaaju ki a sọ̀rọ̀ nipa ohunkohun ninu èto wa loni:

 

Ago,



Mo júbà Èṣù

Èṣù, Mo júbà

Ẹlẹ́gbára ri ajagbọn wa ti o farasin

 Araketu náà ti o ń sọ̀rọ̀ ń sọ̀rọ̀

Èṣù jinnijinni

Kò gba

Laroye!

 

Mo dúpẹ́ Oluwo Awoosore Ifdamitan Daniel Diniz ti wọn ń pe mi lati kopa ninu ipade yìí.

 

Emi ni ọmọ Oduduwa.

Mo ki yin ọmọ ìyá mi kaakiri àwọn orílẹ̀èdè lagbaye

Ẹ ku ọdún tuntun!  

Orúkọ̀ mi ni Adelson Adewale de Brito ti ọpọlọpọ ènìyàn mọ̀ si Ọ̀mọ̀wé Adelson tabi Mọ̀wé Adelson tabi Mawo Adelson.

Mo ki gbogbo ilé, Ẹ kaasan!

Mo ki dọ́kità Ogundeji Ifadamitan Elebuibon

Ẹ kaabọ̀ Ojogbọ́n!

Mo ki yin Ẹ káàbọ̀ pẹ̀lu inudidun pe Mo lo èdè àwọn Bàbá nlá wa lati ki yin “Ẹ́ káàbọ̀” si ìlú Salvador, Olu-ìlú ipinlẹ̀ Baííà.

Ìlú Salvador jẹ́ ìlú ti àwọn aláwọ̀ dúdú pọ̀ jùlọ lagbaye lẹ́hìn Afrika.

Ẹ ku joko, Ojobọn!

Ọmọ orílẹ̀ede Brasili ni mi, ṣùgbọ́n, Mo yangan pe iran Ànàgó ni mi. Emi jẹ́ ara ipelẹ̀ akoko ninu  iran Ànàgó ti wọn mu wa si orílẹ̀ede yìí laarin ni ọgọ́run mẹ́ta ọdún sẹ́hìn, lasiko òwò ẹrú. Olúkọ̀ èdè ati àṣà Ànàgó ni mi.

Ojogbọ́n Ogundeji, Mo ki yin Ẹ kaabọ̀ lorúkọ temi ati lorúkọ àwọn ọmọ ìlú yìí paapa jùlọ̀ lorúkọ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú.

Mo tọrọ gafaara lati dúpẹ́ gidigidi iṣẹ lati ọwọ́ olori ẹsin Ifa náà Babalawo Awosoore Ifadamitan Daniel Diniz “Ẹ ku iṣẹ takun takun, Oluwo”. Mo bẹ́ Ogbọ́n Ọ̀rùnmílá búkun sorí ẹ loni ati lọla ati gbogbo ọjọ́ laarin igbesiaye ẹ.

A kò gbọ̀dọ́ gbàgbé wipe ọdún yìí lọ sọpin. Ọla ni Ọjọ́ tó Ṣáájú Ọdún Tuntun. Bẹ́ẹ̀ni, Ọjọ́ Aiku to nbọ jẹ́ ọjọ́ kinni, oṣu kinni ọdún tuntun.

So, Ọjọ́ Aiku ni ọjọ́ isinmi akọkọ ni eyi ti onikaluku fi sami ayajọ pe oju koowa ri ọdún tuntun.

Mo gbadúrà wipe ọwọ́ ọlọ́rún itura yoo kọ fún olukaluku wa irọrún , aseyori ati alaafia ni gbogbo ìgbà laarin ọdún to ń bọ́.

A kò gbọ̀dọ́ gbàgbé dúpẹ́ fún ni ọwọ́ Ẹlẹ́da wa fún aye wa.

Ojogbọ́n Ogundeji, Emi ò mọ̀ boya yin mọ pe ipinlẹ̀ Baííà jẹ́ Olú-ìlú Yorùbá fún gbogbo àwọn Amẹ́rika...

Ni ọjọ́ kewa, oṣù kẹfà, ọdún 2018 lára abẹwo si orílẹ̀-èdè Brasíìlì, Ọọni ile-Ifẹ náà, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja keji wa si ìlú Salvador lati fi ipinlẹ̀ Baííà lelẹ̀ gẹgẹ̀ bi Olú-ìlú Yorùbá fún gbogbo àwọn Amẹ́rika.

Lati isisiyi lọ Emi yoo sọ ni èdè Oyinbo ati Pọtọgi fún anfaani àwọn ti ko gbọ Yorùbá.

Ẹ ṣẹun Mo dúpẹ!