Mo
ki eyin baba mi, mo ki eyin Ìyá mi.
Mo
ki eyin Ẹgbọn mi ati aburo mi fún ayeye ọdún yìí.
Mo bẹ Èṣù Ẹlẹ́gbára,ki
ó fún wa ni ọ̀na
ti o dará, ti o si ye kooro.
Jẹ́
ki a ki Èṣù ni ṣaaju ki a sọ̀rọ̀ nipa ohunkohun ninu èto wa loni:
Ago,
Mo
júbà Èṣù
Èṣù,
Mo júbà
Ẹlẹ́gbára
ri ajagbọn wa ti o farasin
Araketu náà ti o ń sọ̀rọ̀ ń sọ̀rọ̀
Èṣù
jinnijinni
Kò
gba
Laroye!
Mo
dúpẹ́ Oluwo Awoosore Ifdamitan Daniel Diniz ti wọn ń pe mi lati kopa ninu ipade
yìí.
Emi
ni ọmọ Oduduwa.
Mo
ki yin ọmọ ìyá mi kaakiri àwọn orílẹ̀èdè lagbaye
Ẹ
ku ọdún tuntun!
Orúkọ̀
mi ni Adelson Adewale de Brito ti ọpọlọpọ ènìyàn mọ̀ si Ọ̀mọ̀wé Adelson tabi Mọ̀wé
Adelson tabi Mawo Adelson.
Mo
ki gbogbo ilé, Ẹ kaasan!
Mo ki dọ́kità Ogundeji Ifadamitan
Elebuibon
Ẹ kaabọ̀ Ojogbọ́n!
Mo
ki yin Ẹ káàbọ̀ pẹ̀lu inudidun pe Mo lo èdè àwọn Bàbá nlá wa lati ki yin “Ẹ́
káàbọ̀” si ìlú Salvador, Olu-ìlú ipinlẹ̀ Baííà.
Ìlú
Salvador jẹ́ ìlú ti àwọn aláwọ̀ dúdú pọ̀ jùlọ lagbaye lẹ́hìn Afrika.
Ẹ
ku joko, Ojobọn!
Ọmọ orílẹ̀ede Brasili ni mi, ṣùgbọ́n,
Mo yangan pe iran Ànàgó ni mi. Emi jẹ́ ara ipelẹ̀ akoko ninu iran Ànàgó
ti wọn mu wa si orílẹ̀ede yìí laarin ni ọgọ́run mẹ́ta ọdún sẹ́hìn, lasiko òwò ẹrú.
Olúkọ̀ èdè ati àṣà Ànàgó ni mi.
Ojogbọ́n
Ogundeji, Mo ki yin Ẹ kaabọ̀ lorúkọ temi ati lorúkọ àwọn ọmọ ìlú yìí paapa jùlọ̀
lorúkọ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú.
Mo
tọrọ gafaara lati dúpẹ́ gidigidi iṣẹ lati ọwọ́ olori ẹsin Ifa náà Babalawo Awosoore
Ifadamitan Daniel Diniz “Ẹ ku iṣẹ takun takun, Oluwo”. Mo bẹ́ Ogbọ́n Ọ̀rùnmílá
búkun sorí ẹ loni ati lọla ati gbogbo ọjọ́ laarin igbesiaye ẹ.
A
kò gbọ̀dọ́ gbàgbé wipe ọdún yìí lọ sọpin. Ọla ni Ọjọ́ tó Ṣáájú Ọdún Tuntun. Bẹ́ẹ̀ni,
Ọjọ́ Aiku to nbọ jẹ́ ọjọ́ kinni,
oṣu kinni ọdún tuntun.
So, Ọjọ́
Aiku ni ọjọ́ isinmi akọkọ ni eyi ti onikaluku fi
sami ayajọ pe oju koowa ri ọdún tuntun.
Mo gbadúrà wipe ọwọ́ ọlọ́rún
itura yoo kọ fún olukaluku wa irọrún , aseyori ati alaafia ni gbogbo ìgbà
laarin ọdún to ń bọ́.
A kò gbọ̀dọ́ gbàgbé dúpẹ́
fún ni ọwọ́ Ẹlẹ́da wa fún aye wa.
Ojogbọ́n
Ogundeji, Emi ò mọ̀ boya yin mọ pe ipinlẹ̀ Baííà jẹ́ Olú-ìlú Yorùbá fún gbogbo
àwọn Amẹ́rika...
Ni ọjọ́
kewa, oṣù kẹfà, ọdún 2018 lára abẹwo si orílẹ̀-èdè Brasíìlì,
Ọọni
ile-Ifẹ náà, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja keji wa si ìlú Salvador lati fi ipinlẹ̀
Baííà lelẹ̀ gẹgẹ̀ bi Olú-ìlú Yorùbá fún gbogbo àwọn Amẹ́rika.
Lati
isisiyi lọ Emi yoo sọ ni èdè Oyinbo ati Pọtọgi fún anfaani àwọn ti ko gbọ
Yorùbá.
Ẹ ṣẹun Mo dúpẹ!