Ni Ọjọ́ 4, Oṣù Kẹrin, Ọdún 1968 ni
ìlú Memphis ti ipinlẹ̀ Tenesee ni orilẹ̀ede Amẹ́rika (USA), wọn
ṣekupa Ọ̀mọ̀we Matin Luther King Jr ni agogo 6:01. CST.
Martin Luther
King, Jr.(January 15, 1929 – April 4, 1968) jẹ́ ẹni ọ̀wọ̀, alákitiyan ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, bẹ́ẹ̀ ni ó sí jẹ́ olórí ẹgbẹ́-ìjíndé fún ẹ̀tọ́ ọmọ-àwùjọ
ni ilé Amẹ́ríkà. Gẹ́gẹ́
bí oníwasú Ìjọ Onítẹ̀bọmi, King di alakitiyan fún ẹ́tọ́ ará-ìlú ní ìbẹ̀rẹ̀ ayé
rẹ̀. Ó di ọ̀kan nínú àwọn oludari
pàtàkì jùlọ ti Ija fún àwọn ẹ̀tọ́ (àti ìgbélarugẹ ipò) àwọn adúláwọ̀ ni
ilẹ̀ Amẹ́rika (USA).
Ohun ni o ẹni
asiwaju lawujọ̀ àwọn ọmọ Afrika-Amẹ́rika lati ọdún
1957 de 1968.
Latari iṣẹ takun
takun fún anfaani àwọn aláwọ̀ dúdú ni Amẹ́rika, Dokita, King di Ẹlẹ́bùn
Nobel fún Àlàfíà ni ọdun 1964.
Aláwọ̀
funfun ti orukọ̀ rẹ̀ ni James Earl Ray yìnbọn pa Dr. King, Jr ní ilé-ìtura kan.
Ó ti gbe lọ si Ilé-iwosan St.Joseph, nibiti o
ku ni 7: 05 ni irọlẹ.
Ó ti jẹ́ ọmọ ọdún
39.
References:
1. 1. Martin
Luther King, Jr;
Martin
Luther King, Jr. - Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(accessesd on April 5, 2021);
2. 2. https://yo.wikipedia.org/wiki/Wikipedia:%C3%80w%E1%BB%8Dn_%C3%8C%E1%B9%A3%E1%BA%B9%CC%80l%E1%BA%B9%CC%80_B%C3%ADi_%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%CC%81_%C3%92n%C3%AD/O%E1%B9%A3%C3%B9_K%E1%BA%B9rin
(accessed on April 5, 2021)
No comments:
Post a Comment