https://www.bbc.com/yoruba/56446095
(18/03/2021)
Ìtàn ààrẹ
John Pompe Magufuli dàbi ti Yar'Adua Nàìjíríà àti Atta Mills ti Ghana
Ìtàn àti ikú ààrẹ
John Pompe Magufuli dàbi ti ààrẹ Nàìjíríà nígbà kan ri Umar Musa Yar'Adua,
Pierre Nkurunziza ti Burundi, John Attag ti Ghana àti àwọn ààrẹ mẹ́rin míìràn
ti wọ́n kú sórí oyè.
Bí àwọn ààrẹ ilẹ adúláwọ̀ ṣe máa n lo sáà wọ́n tán lórí oyè, bẹ́ẹ̀ ni
àwọn míràn máa n kú sórí àléfà.
Bí ti ààrẹ Tanzania, John Magufuli se
ku ti aríyànjiyàn sì wà lórí ikú rẹ̀ ni náà lo ri ti kò si ẹni to mọ idí ikú
àwọn olórí orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Afíríkà mííràn.
Okú ni ọjọ́ kétàdinlógún, oṣù kẹta,
ọdún 2021 lẹ́yìn oṣù péréte tó jáwé olúbori nínú ìbò ààrẹ lẹni ọdún
mọ́kànlélọ́gọ́ta.
Gẹ́gẹ́ ìgbákejì ààrẹ ṣe sọ Semia
Suluhu Hassan ààrẹ àná kú látparí àìsàn ọkàn tó ti n bá fíra láti bi ọdún
mẹ́wàá sẹ́yìn.
Ìkéde yìí wáyé lẹ́yin bi ọ̀sẹ méjì ti
kò sí ẹni tó kófìrí rẹ̀ ni àwùjọ, tí àwọn ènìyàn sì bẹ̀rl si ni tẹnubọlẹ̀ nípa
ìlera rẹ̀ àti pé níbo ni ààrẹ wà.
No comments:
Post a Comment