Monday, November 23, 2020

Ọjọ́ Iranti àwon eyan dudu

 


Oşù kokanlá ọdún (November) ní orílẹ̀-èdè Brasili jẹ́ àsìkò ti gbogbo ènìyàn máa şe ìrántí ìtàn àwọn bàbanla àti màmánla adúláwọ̀ ni orílẹ̀-èdè yìí,

Nínú oşù yii, àwọn ara ìlú Brasili máa bojúwo wẹ̀hìn láti ránti onírúrú ohun ti o şẹlẹ̀ si ènìyàn dúdú ni ìgbà oko ẹrú.

Òwò ẹrú jẹ́ okan nunu-òwò to gbajumọ yika agbaye nigbati wọn ti n ko àwọn ọmọ aduláwọ̀ lọ ta bíi ẹrú soke okun.

Aarin ṣaa onka ẹgbẹrun ọdun kẹrindinlogun si ikọkandinlogun (16th-19th century) si ni òwò ẹrú gbilẹ nilẹ Afirika,

Lasiko yii ni wọn si ta adulawọ bii miliọnu mejila (12 million) soko ẹru loke okun nigba naa.

Lori ilẹ̀ Amẹrika, Ìlú Brasili ni orilẹ̀-èdè ti o gbe àwọn ẹrú julọ ti ilẹ̀ Afirika wọle. Lakoko yẹn, ni ayika àwọn miliọnu mẹ́rin (4 million) àwọn ọkunrin, àwọn obinrin ati àwọn ọmọde wa, deede ti o ju idamẹta gbogbo iṣòwò ẹrú lọ.

Lati ọdún ọgọ́rùún kẹrindilogun (16th century), nígbà ti Ọba Pọtugi gba ilẹ̀ yìí lati ọwọ́ àwọn olùgbé àbíníbí, titi ọdún ọgọ́rùún ikọkandinlógún (19th century).

Òwò ẹrú ni ilẹ̀ Brasíì pẹ́ fun díẹ̀ sii jù ọdún ọgọ́rùún mẹ́ta (300 years), o jẹ́ orilẹ̀-èdè to kẹhin ni agbaye lati fopin si oko ẹrú.

Nitorinaa, o túmọ̀ si pé làkókò ọdún ọgọ́rùún mẹ́ta, àwọn aláwọ̀ dúdú ti a mu lati ọ̀pọlọ́pọ́ àgbègbè Ilẹ̀ Afirika ṣiṣẹ fún ijọba amunisin Pọtugi ni ilẹ̀ Brasíì fún ọ̀fẹ́ ati labẹ àwọn ipò àìṣe ènìyàn.

Ni ọjọ́ kẹ̀tala (13), oṣù kárù-ún (May) ọdún 1888 ni Ọmọba Isabel fọwọ́ si ofin lati fopin si ówó ẹrú ni orilẹ̀-èdè Brasili,

Nitori yìí, ni Ẹgba-̃le-logun ọdún (year 2020) ni o jẹ́ ayẹyẹ ọgọrun mejilelọgbọ̀n ọdún (132 years) ti opin si ówó ẹrú ni ilẹ̀ yìí,

Ọmọbinrin Isabel Cristina Leopoldina Augusta Micaela Gabriela Rafaela Gonzaga de Bourbon-Sicilies Meji ati Bragança ni ọmọ ikeji, ọmọbirin akọkọ ti Emperor Pedro II ti Ilú Brasili ati iyawo rẹ Empress Teresa Cristina ti Awọn Sicilies Meji. Gẹgẹbi arole ti ijọba ti Ìlú Brasili, o gba akọle ti Ọmọbinrin ọba

Síbẹ̀síbẹ̀, òfin yẹn kò mu eyikeyi isanpada tabi iṣeduro àwọn anfani ẹ̀tọ́ gẹgẹbi ọmọ orilẹ̀-èdè deede: bawo ni ofin ṣe le munadoko nigbati kò ba fi idi àwọn ohun silẹ̀ ti iṣeduro ẹ̀tọ́ (àti ìgbélarugẹ ipò) àwọn adúláwọ̀ ni ilẹ̀ yìí pẹ̀lú ọ̀nà lati pèsè idogbándógba nípa:

– ẹ̀tọ́ fún adúláwọ̀ lati dibò ;

– àyípadà àwọn òfin ti o ya ọmọ aláwọ̀-dúdú sọ́tọ̀ ni ìlé-ìwé,

ẹyawó láti ra ile,

– àti àwọn ètò ìrànlọ́wọ́ míràn,

Fún àwọn idi wọnyi ati àwọn idi miiran ti àwọn ènìyàn dudu ni orilẹ̀-èdè yìí kò ṣe ayẹyẹ kankan ni oṣù karun-un ọdún (May), ọjọ́13.

Síbẹ̀síbẹ̀, wọn ṣe ayẹyẹ nla kakiri gbogbo ìlú Brasili ni Oṣu kọkanla (November), Ọjọ́ ogun (20).

Ni ọjọ́ yìí ti wọn máa şe ìrántí Zumbi dos Palmares, nitori gbogbo wa, aláwọ̀ dudu ni orilẹ̀-èdè yìí ń gbagbọ pe oun ti bẹrẹ si ija fopin si oko ẹrú, paapaa ni ọrundun kẹrindilogun (16th century).

Zumbi jẹ́ ọkàn ninu àwọn adari dudu nla julọ ni ìtàn ti Ìlú Brasili ti o ja eto ẹrú.

Ọjọ́ 20, Oṣù Mọ̀kànlá dún 1695 ni àwọn jagunjagun a ti o sanwo nipasẹ alaṣe ijọba amunisin pọtugi sekupa Zumbi ni ibi kan nitosi Quilombo dos Palmares naa.

Nitori eyi, Ọjọ́ yìí di yan bi Ọjọ́ Ẹ̀rí-ọkàn dudu naa, ti wa ṣẹda ni ọdún 2003 gẹgẹbi ọjọ́ ti wa ya sọ́tọ̀ ti a fi ń sámi ayẹyẹ ìjà ominira àwọn aláwọ̀ dudu lara ìtàn orilẹ̀-èdè

Ni ìgbà òwò ẹrú àwọn Quilombo ni a ṣeto bi ibi ti pèsè ààbò fún àwọn ẹrú ti o sá wọn kúrò láti ibi ti n ṣiṣé ni oko ẹrú.

Wọn sí dá àwọn adúgbò yìí sílẹ̀ ni orílẹ̀-èdè Brasili patapata.

Èròn̄gbà àkọ́kọ́ ti àwọn oludari Quilombo ni láti fi aye ààbò fún gbogbo àwọn ènìyàn ti o sálọ òwò ẹrú láti ibikibi káàkiri gbogbo llẹ̀ Brasili.

Díẹ̀díẹ̀, àwọn àgbègbè Quilombo yìí bẹ̀rẹ̀sí ni pọ̀síí káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè yìí.

Àwọn òyínbo aláwọ̀ funfun pọtugi ti wọn amunisin ni ìgbà náà bẹ̀rẹ̀sí ni fura pẹ̀lú pipọ̀síí àgbègbè tabi adúgbò Quilombo nípa ewu ti wọn jẹ́ fun àwọn nkan wọn.

Nítorí idi eyi, àwọn òyínbo pọtugi pàṣe pé ibikíbi ti wọn ba ti ri èyiàn márùún ninu àwọn ẹ̀ru papọ̀ ki wọn kàsí pé wọn tìlú sí òfin.

A yìí jade ni dún 1740.

A ka Zumbi bi oludari to kẹhin ti Quilombo dos Palmares

Ọjọ́ ẹ̀ri-ọkàn dudu ni a ń ṣe pataki ami idanimọ̀ àwọn àláwọ̀ dudu ni ìlú Brasili.

O ṣe pàtàki láti mọ diẹ ẹ sii nipa ìtan ti ènìyàn dudu ti o wa láárín  wa.

Ó tó àkókò fún wa aláwọ̀ dudu ni orílẹ̀-èdè yìí láti káràmásiki àwọn ohun ti ogún àwọn bàbá nla wa. 

O jẹ́ àkókò láti mọ diẹ sii nipa ara wa.

Àkíyèsí:

Mo dupẹ lọwọ́ ọ̀rẹ́ mi Oyewale Misbah Akanni ti o fún mi iranlọwọ́ nigbagbogbo ninu igbiyanju mi lati kọ ẹkọ ede Yoruba, bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú atunṣe gbogbo ohun ti Mo gbejade ni ede Yorùbá-Nàgó. 


1 comment:

  1. O je lakoko lati mo dei nipa ara wa
    É tempo de sabermos mais sobre nós

    ReplyDelete